Translated to Yoruba by Olanrewaju AJidagba
Ti ó bá lè mọ́ kàn, tó o si bínú
Nígbà tí àwọn tó wà ní sàkání rẹ bá n dá ẹ́ lẹjọ Nítorí pé wọn n Sojo
Tí ó bá lè nígbagbọ́ nínú ará rẹ, báyé bá tiẹ síyè méjì
Ṣugbọ́n ó Fàyè sílẹ fún ìyè méjì wọn
Tí ó bá lè ní ifárádà lai jẹ kó sún ẹ́
Tó ò si púrọ táyé bá ti ẹ̀ párọ́ mọ́ ẹ́
Ó kọ̀ láti kòrirá táyé bá tiẹ̀ kòrirá rẹ́
Ó si Ṣọrá láti múrá jù lójú Ọmọ aráyé tàbí sọ̀rọ̀ ọ̀lọ́gbọ́n nígbà gbógbó
*
Tí ó bá lè lá àlá,
Láì jẹ kí àlá jọ́bá lè ọ lórí
Tó ó si lè ronú jinlẹ̀
láì jẹ kí ìrònú jẹ́ Kókó ayé rẹ́
Tí ó bá lè pàdé àjálù àti ìṣẹ́gun
Síbẹ̀, ó bá wọ́n lò gẹ́gẹ́ bí ọkàn
Tí ó bá lè f’àyè gbá Ọmọ́ aràyé
láti yí ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ́ nítorí wọ́n
Fẹ́ ṣí àwọn ọdẹ́ lọnà
Tàbí wò gbógbó o n ti ó làágun fun bàjẹ̀
láì bárájẹ́
Sùgbọ́n ò bẹ̀rẹ̀ sí i tòó látí ibẹ̀rẹ̀
pàápàá pẹlú irinṣẹ́ tí kò wúlò mọ́
*
Tí ó bálè kó gbógbó èrè rẹ̀ jọ́
Tó ó sì fi lè tá tẹ́tẹ́,
ó tún múrá tán látí pàdánù rẹ́
láì sí ìnìrá
Síbẹ̀, ó ṣè tán látí pádà sí ibẹrẹ́
láì mẹnúbà ìpàdánù rẹ́
Tí ó bá lè f’ipá mú ọkàn
ati àyà rẹ́
Látí má sìn ẹ́ tẹ̀síwájú
Nígbà tí ó bá rí bẹ́ní pé
kò sí nkán kán nínú rẹ́ mọ̀
Àfí ìgbàgbọ́
tí n wí fún ọ́ pè ‘iwọ́ dúró!’
*
Tí ó bálè sọ̀rọ̀ láàrín èrò
láì sọ̀ ìwà rẹ̀ nù
Tàbí bá awọ́n ọ́bá rìn
láì pàdánù ohún t’ayé ńfẹ́
Tí ọ̀tá rẹ́ tàbí ọrẹ́ tímọ́tímọ́
ò bálè ṣè ọ́ nípá
Tí ọmọ́ aráyé bálè ká pẹlú rẹ́ láì pọ̀jù
Tí ó bá lè fí
ọgọ́tá ìṣẹ̀jú-àáyá èrè jíjìn
dí iṣẹjú tí ó kọ̀ látí dáríjí ní
Ti ẹ́ ní àyé
àtí gbógbó nnkán tí ó wà nínú rẹ̀
Ni pàtàkì, wà á dá Ọkùnrín – Ọmọ mí!
Ipari.